Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 13:48-52 Yorùbá Bibeli (YCE)

48. Nigbati awọn Keferi si gbọ́ eyi, nwọn yọ̀, nwọn si yìn ọ̀rọ Ọlọrun logo: gbogbo awọn ti a yàn si ìye ainipẹkun si gbagbọ́.

49. A si tàn ọ̀rọ Oluwa ka gbogbo ẹkùn na.

50. Ṣugbọn awọn Ju rú awọn obinrin olufọkansin ati ọlọlá soke ati awọn àgba ilu na, nwọn si gbe inunibini dide si Paulu on Barnaba, nwọn si ṣí wọn kuro li àgbegbe wọn.

51. Ṣugbọn nwọn gbọ̀n ekuru ẹsẹ wọn si wọn, nwọn si wá si Ikonioni.

52. Awọn ọmọ-ẹhin si kún fun ayọ̀ ati fun Ẹmí Mimọ́.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 13