Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 12:1-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI akoko igbana ni Herodu ọba si nawọ́ rẹ̀ lati pọn awọn kan loju ninu ijọ.

2. O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johanu.

3. Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ́ mu Peteru pẹlu. O si jẹ ìgba ọjọ àiwukàra.

4. Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja.

5. Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u.

6. Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na.

7. Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀.

8. Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.

9. On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran.

10. Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ.

11. Nigbati oju Peteru si walẹ, o ni, Nigbayi ni mo to mọ̀ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rẹ̀, o si gbà mi li ọwọ́ Herodu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju.

12. Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura.

13. Bi o si ti kàn ilẹkun ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin kan ti a npè ni Roda, o wá dahun.

14. Nigbati o si ti mọ̀ ohùn Peteru, kò ṣí ilẹkun fun ayọ̀, ṣugbọn o sure wọle, o si sọ pe, Peteru duro li ẹnu-ọ̀na.

15. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ nṣiwère. Ṣugbọn o tẹnumọ́ ọ gidigidi pe Bẹ̃ni sẹ. Nwọn si wipe, Angẹli rẹ̀ ni.

16. Ṣugbọn Peteru nkànkun sibẹ, nigbati nwọn si ṣí ilẹkun, nwọn ri i, ẹnu si yà wọn.

17. Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 12