Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 11:19-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju.

20. Ṣugbọn awọn kan mbẹ ninu wọn ti iṣe ara Kipru, ati Kirene; nigbati nwọn de Antioku nwọn sọ̀rọ fun awọn Hellene pẹlu, nwọn nwasu Jesu Oluwa.

21. Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu wọn: ọpọlọpọ awọn ti o gbagbọ́ yipada si Oluwa.

22. Ihìn wọn si de etí ijọ ti o wà ni Jerusalemu: nwọn si rán Barnaba lọ titi de Antioku;

23. Ẹniti, nigbati o de ti o si ri õre-ọfẹ Ọlọrun, o yọ̀, o si gba gbogbo wọn niyanju pe, pẹlu ipinnu ọkàn ni ki nwọn ki o fi ara mọ́ Oluwa.

24. Nitori on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmí Mimọ́, ati fun igbagbọ́: enia pipọ li a si kà kún Oluwa.

25. Barnaba si jade lọ si Tarsu lati wá Saulu.

26. Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian.

27. Li ọjọ wọnni li awọn woli si ti Jerusalemu sọkalẹ wá si Antioku.

28. Nigbati ọkan ninu wọn, ti a npè ni Agabu si dide, o tipa Ẹmi sọ pe, ìyan nla yio mu ká gbogbo aiye: eyiti o si ṣẹ li ọjọ Klaudiu Kesari.

29. Awọn ọmọ-ẹhin si pinnu, olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti to, lati rán iranlọwọ si awọn arakunrin ti o wà ni Judea:

30. Eyiti nwọn si ṣe, nwọn si fi i ranṣẹ si awọn àgba lati ọwọ́ Barnaba on Saulu.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 11