Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 11:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN aposteli ati awọn arakunrin ti o wà ni Judea si gbọ́ pe awọn Keferi pẹlu ti gba ọ̀rọ Ọlọrun.

2. Nigbati Peteru si gòke wá si Jerusalemu, awọn ti ikọla mba a sọ,

3. Wipe, Iwọ wọle tọ̀ awọn enia alaikọlà lọ, o si ba wọn jẹun.

4. Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe,

5. Emi wà ni ilu Joppa, mo ngbadura: mo ri iran kan li ojuran, Ohun elo kan sọkalẹ bi gọgọwu nla, ti a ti igun mẹrẹrin sọ̀ ka ilẹ lati ọrun wá; o si wá titi de ọdọ mi:

6. Mo tẹjumọ ọ, mo si fiyesi i, mo si ri ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aiye, ati ẹranko igbẹ́, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju ọrun.

7. Mo si gbọ́ ohùn kan ti o fọ̀ si mi pe, Dide, Peteru; mã pa, ki o si mã jẹ.

8. Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai.

9. Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ.

10. Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: a sì tun fà gbogbo rẹ̀ soke ọrun.

11. Si wo o, lojukanna ọkunrin mẹta duro niwaju ile ti a gbé wà, ti a rán lati Kesarea si mi.

12. Ẹmí si wi fun mi pe, ki emi ki o ba wọn lọ, ki emi máṣe kọminu ohunkohun. Awọn arakunrin mẹfa wọnyi si ba mi lọ, a si wọ̀ ile ọkunrin na:

Ka pipe ipin Iṣe Apo 11