Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 10:39-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o ṣe, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu; ẹniti nwọn pa, ti nwọn si fi gbékọ sori igi:

40. On li Ọlọrun jinde ni ijọ kẹta, o si fi i hàn gbangba:

41. Kì iṣe fun gbogbo enia, bikoṣe fun awọn ẹlẹri ti a ti ọwọ Ọlọrun yàn tẹlẹ, fun awa, ti a ba a jẹ, ti a si ba a mu lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.

42. O si paṣẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ ãye on okú.

43. On ni gbogbo awọn woli jẹri si pe, nipa orukọ rẹ̀ li ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ, yio ri imukuro ẹ̀ṣẹ gbà.

44. Bi Peteru si ti nsọ ọ̀rọ wọnyi li ẹnu, Ẹmí Mimọ́ bà le gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na.

45. Ẹnu si yà awọn onigbagbọ ti ìkọlà, iye awọn ti o ba Peteru wá, nitoriti a tu ẹbùn Ẹmi Mimọ́ sori awọn Keferi pẹlu.

46. Nitori nwọn gbọ́, nwọn nfọ onirũru ède, nwọn si nyìn Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahùn wipe,

47. Ẹnikẹni ha le ṣòfin omi, ki a má baptisi awọn wọnyi, ti nwọn gbà Ẹmí Mimọ́ bi awa?

48. O si paṣẹ ki a baptisi wọn li orukọ Jesu Kristi. Nigbana ni nwọn bẹ̀ ẹ ki o duro ni ijọ melokan.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 10