Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 1:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. TEOFILU, ìhìn iṣaju ni mo ti rò, niti ohun gbogbo ti Jesu bẹ̀rẹ si iṣe, ati si ikọ́,

2. Titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke, lẹhin ti o ti ti ipa Ẹmi Mimọ́ paṣẹ fun awọn aposteli ti o yàn:

3. Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun:

4. Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi:

5. Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.

6. Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi?

7. O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀.

8. Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.

9. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn.

10. Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn;

11. Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.

12. Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan.

13. Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 1