Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tim 5:15-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nitori awọn miran ti yipada kuro si ẹhin Satani.

16. Bi obinrin kan ti o gbagbọ́ ba ni awọn opó, ki o mã ràn wọn lọwọ, ki a má si di ẹrù le ijọ, ki nwọn ki o le mã ràn awọn ti iṣe opó nitõtọ lọwọ.

17. Awọn alàgba ti o ṣe akoso daradara ni ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe lãlã ni ọ̀rọ ati ni kikọni.

18. Nitoriti iwe-mimọ́ wipe, Iwọ kò gbọdọ dì malu ti ntẹ̀ ọkà li ẹnu. Ati pe, ọ̀ya alagbaṣe tọ si i.

19. Máṣe gbà ẹ̀sun si alàgba kan, bikoṣe lati ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta.

20. Ba awọn ti o ṣẹ̀ wi niwaju gbogbo enia, ki awọn iyokù pẹlu ki o le bẹ̀ru.

21. Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ati awọn angẹli ayanfẹ, ki iwọ ki o mã ṣakiyesi nkan wọnyi, laiṣe ojuṣãju, lai fi ègbè ṣe ohunkohun.

Ka pipe ipin 1. Tim 5