Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tim 1:8-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ṣugbọn awa mọ̀ pe ofin dara, bi enia ba lò o bi ã ti ilo ofin;

9. Bi a ti mọ̀ eyi pe, a kò ṣe ofin fun olododo, bikoṣe fun awọn alailofin ati awọn alaigbọran, fun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ, fun awọn alaimọ́ ati awọn ẹlẹgan, fun awọn apa-baba ati awọn apa-iya, fun awọn apania,

10. Fun awọn àgbere, fun awọn ti nfi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, fun awọn ají-enia tà, fun awọn eke, fun awọn abura eke, ati bi ohun miran ba si wà ti o lodi si ẹkọ́ ti o yè koro,

11. Gẹgẹ bi ihinrere ti ogo Ọlọrun olubukún, ti a fi si itọju mi.

12. Mo dupẹ lọwọ Ẹniti o fun mi li agbara, ani Kristi Jesu Oluwa wa, nitoriti o kà mi si olõtọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ̀;

13. Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ.

14. Ore-ọfẹ Oluwa wa si pọ̀ rekọja pẹlu igbagbọ́ ati ifẹ, ti mbẹ ninu Kristi Jesu.

15. Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki.

16. Ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri ãnu gbà, pe lara mi, bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rẹ̀ hàn bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ́ si ìye ainipẹkun nigba ikẹhin.

17. Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin.

18. Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere;

19. Mã ni igbagbọ́ ati ẹri-ọkàn rere; eyiti awọn ẹlomiran tanu kuro lọdọ wọn ti nwọn si rì ọkọ̀ igbagbọ́ wọn:

20. Ninu awọn ẹniti Himeneu ati Aleksanderu wà; awọn ti mo ti fi le Satani lọwọ, ki a le kọ́ wọn ki nwọn ki o má sọrọ-odi mọ́.

Ka pipe ipin 1. Tim 1