Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tim 1:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PAULU, Aposteli Kristi Jesu, gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa, ati Kristi Jesu ireti wa;

2. Si Timotiu, ọmọ mi tõtọ ninu igbagbọ́: Ore-ọfẹ, ãnu, alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.

3. Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran,

4. Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi.

5. Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa.

6. Lati inu eyiti awọn ẹlomiran ti yapa kuro ti nwọn si ya sapakan si ọrọ asan;

7. Nwọn nfẹ ṣe olukọ ofin; òye ohun ti nwọn nwi kò yé wọn, tabi ti ohun ti nwọn ntẹnumọ́.

8. Ṣugbọn awa mọ̀ pe ofin dara, bi enia ba lò o bi ã ti ilo ofin;

9. Bi a ti mọ̀ eyi pe, a kò ṣe ofin fun olododo, bikoṣe fun awọn alailofin ati awọn alaigbọran, fun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ, fun awọn alaimọ́ ati awọn ẹlẹgan, fun awọn apa-baba ati awọn apa-iya, fun awọn apania,

Ka pipe ipin 1. Tim 1