Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tes 4:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ li akotan, ará, awa mbẹ̀ nyin, awa si ngbà nyin niyanju ninu Jesu Oluwa, pe bi ẹnyin ti gbà lọwọ wa bi ẹnyin iba ti mã rìn, ti ẹnyin iba si mã wù Ọlọrun, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nrìn, ki ẹnyin le mã pọ̀ siwaju si i.

2. Nitori ẹnyin mọ̀ irú aṣẹ ti a ti pa fun nyin lati ọdọ Jesu Oluwa.

3. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere:

4. Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá;

5. Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun:

6. Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu.

Ka pipe ipin 1. Tes 4