Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tes 2:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORI ẹnyin tikaranyin mọ̀, ará, irú iwọle wa si nyin pe kì iṣe lasan:

2. Ṣugbọn lẹhin ti awa ti jìya ṣaju, ti a si ti lo wa ni ilo itiju ni Filippi gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, awa ni igboiya ninu Ọlọrun wa lati sọ̀rọ ihinrere Ọlọrun fun nyin pẹlu ọ̀pọlọpọ ìwàyá ìjà.

3. Nitori ọ̀rọ iyanju wa kì iṣe ti ẹ̀tan, tabi ti ìwa aimọ́, tabi ninu arekereke:

4. Ṣugbọn bi a ti kà wa yẹ lati ọdọ Ọlọrun wá bi ẹniti a fi ihinrere le lọwọ, bẹ̃ li awa nsọ; kì iṣe bi ẹniti nwù enia bikoṣe Ọlọrun, ti ndan ọkàn wa wò.

5. Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri:

6. Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.

7. Ṣugbọn awa nṣe pẹlẹ lọdọ nyin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ntọju awọn ọmọ on tikararẹ:

8. Bẹ̃ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si nyin, inu wa dun jọjọ lati fun nyin kì iṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmí awa tikarawa pẹlu, nitoriti ẹnyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa.

Ka pipe ipin 1. Tes 2