Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Pet 2:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo.

2. Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala,

3. Bi ẹnyin ba ti tọ́ ọ wò pe, olõre li Oluwa:

4. Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye,

5. Ẹnyin pẹlu, bi okuta ãye, li a kọ ni ile ẹmí, alufa mimọ́, lati mã ru ẹbọ ẹmí, ti iṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun nipa Jesu Kristi.

6. Nitori o mbẹ ninu iwe-mimọ́ pe, Kiyesi i, Mo fi pàtaki okuta igunle, àṣayan, iyebiye, lelẹ ni Sioni: ẹniti o ba si gbà a gbọ́ oju kì yio ti i.

Ka pipe ipin 1. Pet 2