Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Pet 1:21-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.

22. Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá.

23. Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.

24. Nitoripe gbogbo ẹran ara dabi koriko, ati gbogbo ogo rẹ̀ bi itanná koriko. Koriko a mã gbẹ, itanná rẹ̀ a si rẹ̀ silẹ:

25. Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa duro titi lai. Ọ̀rọ yi na si ni ihinrere ti a wãsu fun nyin.

Ka pipe ipin 1. Pet 1