12. Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi.
13. Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ?
14. Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere.
15. Ṣugbọn emi kò lò ọ̀kan ninu nkan wọnyi: bẹ̃li emi kò si kọwe nkan wọnyi, nitori ki a le ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun mi: nitoripe o san fun mi ki emi kuku kú, jù ki ẹnikẹni ki o sọ ogo mi di asan.
16. Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere, emi kò li ohun ti emi ó fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mogbé! bi emi kò ba wasu ihinrere.
17. Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ.
18. Njẹ kini ha li ère mi? pe, nigbati mo ba nwasu ihinrere Kristi fun-ni laini inawo, ki emi ki o máṣe lo agbara mi ninu ihinrere ni kikun.
19. Nitori bi mo ti jẹ omnira kuro lọdọ gbogbo enia, mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo wọn, ki emi ki o le jère pipọ si i.
20. Ati fun awọn Ju mo dabi Ju, ki emi ki o le jère awọn Ju; fun awọn ti mbẹ labẹ ofin, bi ẹniti mbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jère awọn ti mbẹ labẹ ofin;
21. Fun awọn alailofin bi alailofin (emi kì iṣe alailofin si Ọlọrun, ṣugbọn emi mbẹ labẹ ofin si Kristi) ki emi ki o le jère awọn alailofin.
22. Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jère awọn alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo enia, ki emi ki o le gbà diẹ là bi o ti wu ki o ri.
23. Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin.