Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 9:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. APOSTELI kọ́ emi iṣe bi? emi kò ha wà li omnira? emi ko ti ri Jesu Kristi Oluwa wa? iṣẹ mi kọ́ ẹnyin iṣe ninu Oluwa?

2. Bi emi ki iṣe Aposteli fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn dajudaju Aposteli li emi iṣe fun nyin: nitori èdidi iṣẹ Aposteli mi li ẹnyin iṣe ninu Oluwa.

3. Èsi mi fun awọn ti nwadi mi li eyi:

4. Awa kò ha li agbara lati mã jẹ ati lati mã mu?

5. Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa?

6. Tabi emi nikan ati Barnaba, awa kò ha li agbara lati joko li aiṣiṣẹ?

7. Tani ilọ si ogun nigba kan rí ni inawo ara rẹ̀? tani igbìn ọgba ajara, ti ki isi jẹ ninu eso rẹ̀? tabi tani mbọ́ ọ̀wọ́-ẹran, ti kì isi jẹ ninu wàra ọ̀wọ́-ẹran na?

Ka pipe ipin 1. Kor 9