Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 7:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ṣugbọn mo sọ eyi bi imọran, kì iṣe bi aṣẹ.

7. Nitori mo fẹ ki gbogbo enia ki o dabi emi tikarami. Ṣugbọn olukuluku enia ni ẹ̀bun tirẹ̀ lati ọdọ Ọlọrun wá, ọkan bi irú eyi, ati ekeji bi irú eyini.

8. Ṣugbọn mo wi fun awọn apọ́n ati opó pe, O dara fun wọn bi nwọn ba wà gẹgẹ bi emi ti wà.

9. Ṣugbọn bi nwọn kò bá le maraduro, ki nwọn ki o gbeyawo: nitori o san lati gbeyawo jù ati ṣe ifẹkufẹ lọ.

10. Ṣugbọn awọn ti o ti gbeyawo ni mo si paṣẹ fun, ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe Oluwa, Ki aya máṣe fi ọkọ rẹ̀ silẹ.

11. Ṣugbọn bi o bá si fi i silẹ ki o wà li ailọkọ, tabi ki o ba ọkọ rẹ̀ làja: ki ọkọ ki o máṣe kọ̀ aya rẹ̀ silẹ.

12. Ṣugbọn awọn iyokù ni mo wi fun, kì iṣe Oluwa: bi arakunrin kan ba li aya ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe kọ̀ ọ silẹ.

13. Ati obinrin ti o ni ọkọ ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe fi i silẹ.

14. Nitoriti a sọ alaigbagbọ́ ọkọ na di mimọ́ ninu aya rẹ̀, a si sọ alaigbagbọ́ aya na di mimọ́ ninu ọkọ rẹ̀: bikoṣe bẹ̃ awọn ọmọ nyin iba jẹ alaimọ́; ṣugbọn nisisiyi nwọn di mimọ́.

15. Ṣugbọn bi alaigbagbọ́ na ba lọ, jẹ ki o mã lọ. Arakunrin tabi arabinrin kan kò si labẹ ìde, nitori irú ọ̀ran bawọnni: ṣugbọn Ọlọrun pè wa si alafia.

Ka pipe ipin 1. Kor 7