16. Nitori iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ aya, bi iwọ ó gbà ọkọ rẹ là? tabi iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ ọkọ, bi iwọ ó gbà aya rẹ là?
17. Ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti pín fun olukuluku enia, bi Oluwa ti pè olukuluku, bẹ̃ni ki o si mã rìn. Bẹ̃ni mo si nṣe ìlana ninu gbogbo ijọ.
18. A ha pè ẹnikan ti o ti kọla? ki o má si ṣe di alaikọla. A ha pè ẹnikan ti kò kọla? ki o máṣe kọla.
19. Ikọla ko jẹ nkan, ati aikọla kò jẹ nkan, bikoṣe pipa ofin Ọlọrun mọ́.
20. Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e.
21. A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini.
22. Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi.
23. A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia.
24. Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun.
25. Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo.
26. Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃.