Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 3:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Bi ẹnikan bá ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, on ni Ọlọrun yio parun; nitoripe mimọ́ ni tẹmpili Ọlọrun, eyiti ẹnyin jẹ.

18. Ki ẹnikẹni máṣe tàn ara rẹ̀ jẹ. Bi ẹnikẹni ninu nyin laiye yi ba rò pe on gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, ki o le ba gbọ́n.

19. Nitori ọgbọ́n aiye yi wèrè ni lọdọ Ọlọrun. Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹniti o mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke wọn.

20. A si tún kọ ọ pe, Oluwa mọ̀ ero ironu awọn ọlọgbọ́n pe, asan ni nwọn.

21. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe ṣogo ninu enia. Nitori tinyin li ohun gbogbo,

22. Iba ṣe Paulu, tabi Apollo, tabi Kefa, tabi aiye, tabi ìye, tabi ikú, tabi ohun isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ̀; tinyin ni gbogbo wọn;

23. Ẹnyin si ni ti Kristi; Kristi si ni ti Ọlọrun.

Ka pipe ipin 1. Kor 3