Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 3:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ARÁ, emi kò si le ba nyin sọ̀rọ bi awọn ti iṣe ti Ẹmí, bikoṣe bi awọn ti iṣe ti ara, ani bi awọn ọmọ-ọwọ ninu Kristi.

2. Wàra ni mo ti fi bọ́ nyin, kì iṣe onjẹ: nitori ẹ kò iti le gbà a, nisisiyi na ẹ kò iti le gbà a.

3. Nitori ẹnyin jẹ ti ara sibẹ: nitori niwọnbi ilara ati ìja ati ìyapa ba wà larin nyin, ẹnyin kò ha jẹ ti ara ẹ kò ha si nrìn gẹgẹ bi enia?

4. Nitori nigbati ẹnikan nwipe, Emi ni ti Paulu; ti ẹlomiran si nwipe, Emi ni ti Apollo; ẹnyin kò ha iṣe enia bi?

5. Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun.

6. Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá.

7. Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá.

8. Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirẹ̀ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ̀.

9. Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin.

10. Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e.

11. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.

Ka pipe ipin 1. Kor 3