Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 15:37-55 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Ati eyiti iwọ fọnrugbin, ara ti mbọ̀ ki iwọ fọnrugbin, ṣugbọn irugbin lasan ni, ibã ṣe alikama, tabi irú miran.

38. Ṣugbọn Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirẹ̀.

39. Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ.

40. Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ: ṣugbọn ogo ti oke ọrun ọ̀tọ, ati ogo ti aiye ọ̀tọ.

41. Ọtọ li ogo ti õrùn, ọ̀tọ li ogo ti oṣupa, ọ̀tọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo.

42. Gẹgẹ bẹ̃ si li ajinde okú. A gbìn i ni idibajẹ; a si jí i dide li aidibajẹ:

43. A gbìn i li ainiyìn; a si jí i dide li ogo: a gbìn i li ailera, a si jí i dide li agbara:

44. A gbìn i li ara iyara; a si jí i dide li ara ẹmí. Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmí si mbẹ.

45. Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye.

46. Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí.

47. Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni.

48. Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun.

49. Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun.

50. Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹ̀jẹ kò le jogún ijọba Ọlọrun; bẹ̃ni idibajẹ kò le jogún aidibajẹ.

51. Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada,

52. Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà.

53. Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀.

54. Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ̀, ti ara kikú yi ba si ti gbe aikú wọ̀ bẹ̃ tan, nigbana ni ọ̀rọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbé ikú mì ni iṣẹgun.

55. Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà?

Ka pipe ipin 1. Kor 15