Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 14:25-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.

26. Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro.

27. Bi ẹnikan ba fi ède fọ̀, ki o jẹ enia meji, tabi bi o pọ̀ tan, ki o jẹ mẹta, ati eyini li ọkọ̃kan; si jẹ ki ẹnikan gbufọ.

28. Ṣugbọn bi kò ba si ogbufọ, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ninu ijọ; si jẹ ki o mã bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọrọ.

29. Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ.

30. Bi a bá si fi ohunkohun hàn ẹniti o joko nibẹ, jẹ ki ẹni iṣaju dakẹ.

31. Gbogbo nyin le mã sọtẹlẹ li ọkọ̃kan, ki gbogbo nyin le mã kọ ẹkọ ki a le tu gbogbo nyin ni inu.

32. Ẹmí awọn woli a si ma tẹriba fun awọn woli.

33. Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́.

34. Jẹ ki awọn obinrin nyin dakẹ ninu ijọ: nitori a kò fifun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wà labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi.

35. Bi nwọn ba si fẹ kọ́ ohunkohun, ki nwọn ki o bère lọwọ ọkọ wọn ni ile: nitori ohun itiju ni fun awọn obinrin lati mã sọrọ ninu ijọ.

36. Kini? lọdọ nyin li ọ̀rọ Ọlọrun ti jade ni? tabi ẹnyin nikan li o tọ̀ wá?

37. Bi ẹnikẹni ba ro ara rẹ̀ pe on jẹ woli, tabi on jẹ ẹniti o li ẹmí, jẹ ki nkan wọnyi ti mo kọ si nyin ki o ye e daju pe ofin Oluwa ni nwọn.

38. Ṣugbọn bi ẹnikan ba jẹ òpe, ẹ jẹ ki o jẹ òpe.

39. Nitorina, ará, ẹ mã fi itara ṣafẹri lati sọtẹlẹ ki ẹ má si ṣe danilẹkun lati fi ède fọ̀.

40. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ.

Ka pipe ipin 1. Kor 14