Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 13:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan.

10. Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin.

11. Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ.

12. Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.

13. Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.

Ka pipe ipin 1. Kor 13