Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 11:23-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara:

24. Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.

25. Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.

26. Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de.

27. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹ akara, ti o si mu ago Oluwa laiyẹ, yio jẹbi ara ati ẹ̀jẹ Oluwa.

28. Ṣugbọn ki enia ki o wadi ara rẹ̀ daju, bẹ̃ni ki o si jẹ ninu akara na, ki o si mu ninu ago na.

29. Nitori ẹnikẹni ti o ba njẹ, ti o ba si nmu laimọ̀ ara Oluwa yatọ, o njẹ o si nmu ẹbi fun ara rẹ̀.

30. Nitori idi eyi li ọ̀pọlọpọ ninu nyin ṣe di alailera ati olokunrun, ti ọ̀pọlọpọ si sùn.

31. Ṣugbọn bi awa ba wadi ara wa, a kì yio da wa lẹjọ.

32. Ṣugbọn nigbati a ba ndá wa lẹjọ, lati ọwọ́ Oluwa li a ti nnà wa, ki a má bã dá wa lẹbi pẹlu aiye.

33. Nitorina, ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba pejọ lati jẹun, ẹ mã duro dè ara nyin.

34. Bi ebi ba npa ẹnikẹni, ki o jẹun ni ile; ki ẹnyin ki o má bã pejọ fun ẹbi. Iyokù li emi ó si tò lẹsẹsẹ nigbati mo ba de.

Ka pipe ipin 1. Kor 11