Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 8:7-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji.

8. Nitoriti o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.

9. Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi.

10. Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi:

11. Olukuluku kì yio si mã kọ́ ara ilu rẹ̀ ati olukuluku arakunrin rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ̀ mi, lati kekere de àgba.

12. Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.

13. Li eyi ti o wipe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai. Ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan.

Ka pipe ipin Heb 8