17. Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.
18. Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀.
19. (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun.
20. Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni.
21. (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:)
22. Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù.
23. Ati nitõtọ awọn pupọ̀ li a ti fi jẹ alufa, nitori nwọn kò le wà titi nitori ikú:
24. Ṣugbọn on, nitoriti o wà titi lai, o ni oyè alufa ti a kò le rọ̀ nipò.
25. Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn.