Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 7:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u;

2. Ẹniti Abrahamu si pin idamẹwa ohun gbogbo fun; li ọna ekini ni itumọ rẹ̀ ọba ododo, ati lẹhinna pẹlu ọba Salemu, ti iṣe ọba alafia;

3. Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi.

4. Njẹ ẹ gbà a rò bi ọkunrin yi ti pọ̀ to, ẹniti Abrahamu baba nla fi idamẹwa ninu awọn aṣayan ikogun fun.

5. Ati nitõtọ awọn ti iṣe ọmọ Lefi, ti o gbà oyè alufa, nwọn ni aṣẹ lati mã gbà idamẹwa lọwọ awọn enia gẹgẹ bi ofin, eyini ni, lọwọ awọn arakunrin wọn, bi o tilẹ ti jẹ pe, nwọn ti inu Abrahamu jade.

6. Ṣugbọn on ẹniti a kò tilẹ pitan iran rẹ̀ lati ọdọ wọn wá, ti gbà idamẹwa lọwọ Abrahamu, o si ti sure fun ẹniti o gbà ileri.

7. Ati li aisijiyan rara ẹniti kò to ẹni li ã sure fun lati ọdọ ẹniti o jù ni.

8. Ati nihin, awọn ẹni kikú gbà idamẹwa; ṣugbọn nibẹ̀, ẹniti a jẹri rẹ̀ pe o mbẹ lãye.

9. Ati bi a ti le wi, Lefi papa ti ngbà idamẹwa, ti san idamẹwa nipasẹ Abrahamu.

10. Nitori o sá si mbẹ ni inu baba rẹ̀, nigbati Melkisedeki pade rẹ̀.

11. Njẹ ibaṣepe pipé mbẹ nipa oyè alufa Lefi, (nitoripe labẹ rẹ̀ li awọn enia gbà ofin), kili o si tún kù mọ́ ti alufa miran iba fi dide nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti a kò si wipe nipa ẹsẹ Aaroni?

12. Nitoripe bi a ti pàrọ oyè alufa, a kò si le ṣai pàrọ ofin.

Ka pipe ipin Heb 7