Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 5:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bi o ti wi pẹlu nibomiran pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.

7. Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀,

8. Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya;

9. Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀:

10. Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.

11. Niti ẹniti awa ni ohun pupọ̀ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitoripe ẹ yigbì ni gbigbọ́.

12. Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile.

13. Nitori olukuluku ẹniti nmu wàra jẹ́ alailoye ọ̀rọ ododo: nitori ọmọ-ọwọ ni.

14. Ṣugbọn onjẹ lile ni fun awọn ti o dagba, awọn ẹni nipa ìriri, ti nwọn nlò ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ sarin rere ati buburu.

Ka pipe ipin Heb 5