Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 3:11-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Bi mo ti bura ni ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi.

12. Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye.

13. Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ.

14. Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin;

15. Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu.

16. Nitori awọn tani bi nyin ninu nigbati nwọn gbọ́? Ki ha iṣe gbogbo awọn ti o ti ipasẹ Mose jade lati Egipti wá?

Ka pipe ipin Heb 3