Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 13:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀.

16. Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ.

17. Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin.

18. Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo.

19. Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.

20. Njẹ Ọlọrun alafia, ẹniti o tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan, ti inu okú wá, nipa ẹ̀jẹ majẹmu aiyeraiye, ani Oluwa wa Jesu,

21. Ki o mu nyin pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀, ki o mã ṣiṣẹ ohun ti iṣe itẹwọgba niwaju rẹ̀ ninu wa nipasẹ Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.

22. Emi si mbẹ nyin, ará, ẹ gbà ọ̀rọ iyanju mi; nitori iwe kukuru ni mo kọ si nyin.

23. Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin.

24. Ẹ kí gbogbo awọn ti nṣe olori nyin, ati gbogbo awọn enia mimọ́. Awọn ti o ti Itali wá kí nyin.

25. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Ka pipe ipin Heb 13