Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 13:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KI ifẹ ará ki o wà titi.

2. Ẹ máṣe gbagbé lati mã ṣe alejò; nitoripe nipa bẹ̃ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejò laimọ̀.

3. Ẹ mã ranti awọn onde bi ẹniti a dè pẹlu wọn, ati awọn ti a npọn loju bi ẹnyin tikaranyin pẹlu ti mbẹ ninu ara.

4. Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ.

5. Ki ọkàn nyin ki o máṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ.

6. Nitorina ni awa ṣe nfi igboiya wipe, Oluwa li oluranlọwọ mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi?

7. Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn.

8. Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai.

9. Ẹ máṣe jẹ ki a fi onirũru ati ẹkọ́ àjeji gbá nyin kiri. Nitori o dara ki a mu nyin li ọkàn le nipa ore-ọfẹ, kì iṣe nipa onjẹ, ninu eyiti awọn ti o ti nrìn ninu wọn kò li ère.

10. Awa ni pẹpẹ kan, ninu eyi ti awọn ti nsìn agọ́ kò li agbara lati mã jẹ.

Ka pipe ipin Heb 13