Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 10:2-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Bikoṣe bẹ̃, a kì bá ha ti dẹkun ati mã rú wọn, nitori awọn ti nsìn kì bá tí ni ìmọ ẹ̀ṣẹ, nigbati a ba ti wẹ wọn mọ lẹ̃kanṣoṣo.

3. Ṣugbọn ninu ẹbọ wọnni ni a nṣe iranti ẹ̀ṣẹ li ọdọdún.

4. Nitori ko ṣe iṣe fun ẹ̀jẹ akọ malu ati ti ewurẹ lati mu ẹ̀ṣẹ kuro.

5. Nitorina nigbati o wá si aiye, o wipe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ṣugbọn ara ni iwọ ti pèse fun mi:

6. Ẹbọ sisun ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ ni iwọ kò ni inu didùn si.

7. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i (ninu iwe-kiká nì li a gbé kọ ọ nipa ti emi) Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun.

8. Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin).

9. Nigbana ni o wipe, Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. O mu ti iṣaju kuro, ki o le fi idi ekeji mulẹ.

10. Nipa ifẹ na li a ti sọ wa di mimọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ̃kanṣoṣo.

11. Ati olukuluku alufa si nduro li ojojumọ́ o nṣe ìsin, o si nṣe ẹbọ kanna nigbakugba, ti kò le mu ẹ̀ṣẹ kuro lai:

12. Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun;

13. Lati igbà na lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọtá rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀.

14. Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai.

15. Ẹmí Mimọ́ si njẹri fun wa pẹlu: nitori lẹhin ti o ti wipe,

16. Eyi ni majẹmu ti emi ó ba wọn dá lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si wọn li ọkàn, inu wọn pẹlu li emi o si kọ wọn si;

17. Ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.

18. Ṣugbọn nibiti imukuro iwọnyi ba gbé wà, irubọ fun ẹ̀ṣẹ kò si mọ́.

19. Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu,

Ka pipe ipin Heb 10