Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 10:19-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu,

20. Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀;

21. Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun;

22. Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.

23. Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;)

24. Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere:

25. Ki a má mã kọ ipejọpọ̀ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mã gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile.

26. Nitori bi awa ba mọ̃mọ̀ dẹṣẹ lẹhin igbati awa ba ti gbà ìmọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ mọ́,

27. Bikoṣe ireti idajọ ti o ba ni lẹrù, ati ti ibinu ti o muná, ti yio pa awọn ọtá run.

28. Ẹnikẹni ti o ba gàn ofin Mose, o kú li aisi ãnu nipa ẹri ẹni meji tabi mẹta:

29. Melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ̀ ni ìya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimọ́ si ohun aimọ́, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ.

Ka pipe ipin Heb 10