Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 10:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORI ofin bi o ti ni ojiji awọn ohun rere ti mbọ̀ laijẹ aworan pãpã awọn nkan na, nwọn kò le fi ẹbọ kanna ti nwọn nru nigbagbogbo li ọdọ̃dún mu awọn ti nwá sibẹ̀ di pipé.

2. Bikoṣe bẹ̃, a kì bá ha ti dẹkun ati mã rú wọn, nitori awọn ti nsìn kì bá tí ni ìmọ ẹ̀ṣẹ, nigbati a ba ti wẹ wọn mọ lẹ̃kanṣoṣo.

3. Ṣugbọn ninu ẹbọ wọnni ni a nṣe iranti ẹ̀ṣẹ li ọdọdún.

4. Nitori ko ṣe iṣe fun ẹ̀jẹ akọ malu ati ti ewurẹ lati mu ẹ̀ṣẹ kuro.

5. Nitorina nigbati o wá si aiye, o wipe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ṣugbọn ara ni iwọ ti pèse fun mi:

6. Ẹbọ sisun ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ ni iwọ kò ni inu didùn si.

7. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i (ninu iwe-kiká nì li a gbé kọ ọ nipa ti emi) Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun.

8. Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin).

9. Nigbana ni o wipe, Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. O mu ti iṣaju kuro, ki o le fi idi ekeji mulẹ.

10. Nipa ifẹ na li a ti sọ wa di mimọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ̃kanṣoṣo.

11. Ati olukuluku alufa si nduro li ojojumọ́ o nṣe ìsin, o si nṣe ẹbọ kanna nigbakugba, ti kò le mu ẹ̀ṣẹ kuro lai:

12. Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun;

13. Lati igbà na lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọtá rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Heb 10