Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 4:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin,

5. Lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gbà isọdọmọ.

6. Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba.

7. Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi.

8. Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda.

9. Ṣugbọn nisisiyi, nigbati ẹnyin ti mọ̀ Ọlọrun tan, tabi ki a sá kuku wipe, ẹ di mimọ̀ fun Ọlọrun, ẽha ti ri ti ẹ fi tun yipada si alailera ati alagbe ipilẹṣẹ ẹda, labẹ eyiti ẹnyin tun fẹ pada wa sinru?

10. Ẹnyin nkiyesi ọjọ, ati oṣù, ati akokò, ati ọdún.

11. Ẹru nyin mba mi, ki o má ba ṣe pe lasan ni mo ti ṣe lãlã lori nyin.

12. Ará, mo bẹ̀ nyin, ẹ dà bi emi; nitori emi dà bi ẹnyin: ẹnyin kò ṣe mi ni ibi kan.

13. Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe.

14. Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu.

Ka pipe ipin Gal 4