Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 4:18-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ṣugbọn o dara lati mã fi itara wá ni fun rere nigbagbogbo, kì si iṣe nigbati mo wà pẹlu nyin nikan.

19. Ẹnyin ọmọ mi kekeke, ẹnyin ti mo tún nrọbi titi a o fi ṣe ẹda Kristi ninu nyin.

20. Iba wù mi lati wà lọdọ nyin nisisiyi, ki emi ki o si yi ohùn mi pada nitoripe mo dãmu nitori nyin.

21. Ẹ wi fun mi, ẹnyin ti nfẹ wà labẹ ofin, ẹ kò ha gbọ́ ofin?

22. Nitori a ti kọ ọ pe, Abrahamu ni ọmọ ọkunrin meji, ọkan lati ọdọ ẹrú-binrin, ati ọkan lati ọdọ omnira-obinrin.

23. Ṣugbọn a bí eyiti iṣe ti ẹrúbinrin nipa ti ara; ṣugbọn eyi ti omnira-obinrin li a bí nipa ileri.

24. Nkan wọnyi jẹ apẹrẹ: nitoripe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeji; ọkan lati ori oke Sinai wá, ti a bí li oko-ẹrú, ti iṣe Hagari.

25. Nitori Hagari yi ni òke Sinai Arabia, ti o si duro fun Jerusalemu ti o wà nisisiyi, ti o si wà li oko-ẹrú pẹlu awọn ọmọ rẹ̀.

26. Ṣugbọn Jerusalemu ti oke jẹ omnira, eyiti iṣe iya wa.

27. Nitori a ti kọ ọ pe, Mã yọ̀, iwọ àgan ti kò bímọ: bú si ayọ̀ ki o si kigbe soke, iwọ ti kò rọbi rí; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ jù ti abilekọ lọ.

28. Njẹ ará, ọmọ ileri li awa gẹgẹ bi Isaaki.

29. Ṣugbọn bi eyiti a bí nipa ti ara ti ṣe inunibini nigbana si eyiti a bí nipa ti Ẹmi, bẹ̃ si ni nisisiyi.

30. Ṣugbọn iwe-mimọ́ ha ti wi? Lé ẹrú-binrin na jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrú-binrin kì yio ba ọmọ omnira-obinrin jogun pọ̀.

Ka pipe ipin Gal 4