Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 1:16-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Lati fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, ki emi le mã wasu rẹ̀ larin awọn Keferi; lojukanna emi kò bá ara ati ẹ̀jẹ gbìmọ pọ̀:

17. Bẹ̃ni emi kò gòke lọ si Jerusalemu tọ̀ awọn ti iṣe Aposteli ṣaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arabia, mo si tún pada wá si Damasku.

18. Lẹhin ọdún mẹta, nigbana ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ kí Peteru, mo si gbé ọdọ rẹ̀ ni ijọ mẹdogun.

19. Ṣugbọn emi kò ri ẹlomiran ninu awọn Aposteli miran, bikoṣe Jakọbu arakunrin Oluwa.

20. Nkan ti emi nkọ̀we si nyin yi, kiyesi i, niwaju Ọlọrun emi kò ṣeke.

21. Lẹhin na mo si wá si ẹkùn Siria ati ti Kilikia;

Ka pipe ipin Gal 1