Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 1:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Njẹ nisisiyi enia ni emi nyi lọkàn pada tabi Ọlọrun? tabi enia ni emi nfẹ lati wù? nitoripe bi emi ba si nwù enia, emi kì yio le ṣe iranṣẹ Kristi.

11. Ṣugbọn, ará, mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe ihinrere ti mo ti wasu kì iṣe nipa ti enia.

12. Nitori kì iṣe lọwọ enia ni mo ti gbà a, bẹ̃li a kò fi kọ́ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kristi.

13. Nitori ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ãlà, ti mo si bà a jẹ:

14. Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi.

15. Ṣugbọn nigbati o wù Ọlọrun, ẹniti o yà mi sọtọ lati inu iya mi wá, ti o si pè mi nipa ore-ọfẹ rẹ̀,

16. Lati fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, ki emi le mã wasu rẹ̀ larin awọn Keferi; lojukanna emi kò bá ara ati ẹ̀jẹ gbìmọ pọ̀:

Ka pipe ipin Gal 1