Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 1:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú),

2. Ati gbogbo awọn arakunrin ti o wà pẹlu mi, si awọn ijọ Galatia:

3. Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Jesu Kristi Oluwa wa,

4. Ẹniti o fi on tikalarẹ̀ fun ẹ̀ṣẹ wa, ki o le gbà wa kuro ninu aiye buburu isisiyi, gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun ati Baba wa:

5. Ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.

6. Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pè nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran:

7. Eyiti kì iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada.

8. Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.

9. Bi awa ti wi ṣaju, bẹ̃ni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.

Ka pipe ipin Gal 1