Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efe 3:3-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Bi o ti ṣepe nipa ifihan li o ti fi ohun ijinlẹ nì hàn fun mi, (gẹgẹ bi mo ti kọ ṣaju li ọrọ diẹ,

4. Nigbati ẹnyin ba kà a, nipa eyi ti ẹnyin ó fi le mọ oye mi ninu ijinlẹ Kristi,)

5. Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí;

6. Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere:

7. Iranṣẹ eyiti a fi mi ṣe gẹgẹ bi ẹ̀bun ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀.

8. Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi;

9. Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ-iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ́ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi:

10. Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ,

11. Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa:

12. Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Efe 3