Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efe 3:14-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi,

15. Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye,

16. Ki on ki o le fifun nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ ogo rẹ̀, ki a le fi agbara rẹ̀ mú nyin li okun nipa Ẹmí rẹ̀ niti ẹni inu;

17. Ki Kristi ki o le mã gbé inu ọkàn nyin nipa igbagbọ; pe bi ẹ ti nfi gbongbo mulẹ, ti ẹ si nfi ẹsẹ mulẹ ninu ifẹ,

18. Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ,

19. Ati lati mọ ifẹ Kristi ti o ta ìmọ yọ, ki a le fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọrun kun nyin.

20. Njẹ ẹniti o le ṣe lọpọlọpọ jù gbogbo eyiti a mbère tabi ti a nrò lọ, gẹgẹ bi agbara ti nṣiṣẹ ninu wa,

21. On ni ki a mã fi ogo fun ninu ijọ ati ninu Kristi Jesu titi irandiran gbogbo, aiye ainipẹkun. Amin.

Ka pipe ipin Efe 3