Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efe 3:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORI eyina, emi Paulu, ondè Jesu Kristi nitori ẹnyin Keferi,

2. Bi ẹnyin ba ti gbọ ti iṣẹ iriju ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun mi fun nyin:

3. Bi o ti ṣepe nipa ifihan li o ti fi ohun ijinlẹ nì hàn fun mi, (gẹgẹ bi mo ti kọ ṣaju li ọrọ diẹ,

4. Nigbati ẹnyin ba kà a, nipa eyi ti ẹnyin ó fi le mọ oye mi ninu ijinlẹ Kristi,)

5. Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí;

6. Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere:

Ka pipe ipin Efe 3