Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efe 1:14-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.

15. Nitori eyi, emi pẹlu, nigbati mo ti gburó igbagbọ ti mbẹ larin nyin ninu Jesu Oluwa, ati ifẹ nyin si gbogbo awọn enia mimọ́,

16. Emi kò si simi lati mã dupẹ nitori nyin, ati lati mã darukọ nyin ninu adura mi;

17. Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀:

18. Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ,

19. Ati agbara rẹ̀ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ́, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀,

20. Eyiti o ti ṣiṣẹ ninu Kristi, nigbati o ti jí dide kuro ninu okú, ti o si fi i joko li ọwọ́ ọtún ninu awọn ọrun,

21. Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu.

22. O si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀, o si ti fi i ṣe ori lori ohun gbogbo fun ijọ,

23. Eyiti iṣe ara rẹ̀, ẹkún ẹniti o kún ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.

Ka pipe ipin Efe 1