Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.