Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 8:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tun tọ̀ mi wá, wipe,

2. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; owu nlanla ni mo jẹ fun Sioni, ikannu nlanla ni mo fi jowu fun u.

3. Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.

4. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, arugbo ọkunrin ati arugbo obinrin, yio sa gbe igboro Jerusalemu, ati olukuluku ti on ti ọ̀pa li ọwọ rẹ̀ fun ogbó.

5. Igboro ilu yio si kún fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebinrin, ti nṣire ni ita wọn.

6. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, bi o ba ṣe iyanu li oju iyokù awọn enia yi li ọjọ wọnyi, iba jẹ iyanu li oju mi pẹlu bi? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

7. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Kiye si i, emi o gbà awọn enia mi kuro ni ilẹ ila-õrun, ati kuro ni ilẹ yama;

Ka pipe ipin Sek 8