Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 7:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.

12. Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá.

13. O si ṣe, gẹgẹ bi o ti kigbe, ti nwọn kò si fẹ igbọ́, bẹ̃ni nwọn kigbe, ti emi kò si fẹ igbọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

14. Mo si fi ãja tú wọn ka si gbogbo orilẹ-ède ti nwọn kò mọ̀. Ilẹ na si dahoro lẹhin wọn, ti ẹnikẹni kò là a kọja tabi ki o pada bọ̀: nwọn si sọ ilẹ ãyò na dahoro.

Ka pipe ipin Sek 7