Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 6:7-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye.

8. Nigbana ni on si kọ́ si mi, o si ba mi sọ̀rọ, wipe, Wò o, awọn wọnyi ti o lọ sihà ilẹ ariwa ti mu ẹmi mi parọrọ ni ilẹ ariwa.

9. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

10. Mu ninu igbèkun, ninu awọn ti Heldai, ti Tobijah, ati ti Jedaiah, ti o ti Babiloni de, ki iwọ si wá li ọjọ kanna, ki o si wọ ile Josiah ọmọ Sefaniah lọ;

11. Ki o si mu fàdakà ati wurà, ki o si fi ṣe ade pupọ̀, ki o si gbe wọn kà ori Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa:

12. Si sọ fun u pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Wò ọkunrin na ti orukọ rẹ̀ njẹ ẸKA; yio si yọ ẹka lati abẹ rẹ̀ wá, yio si kọ́ tempili Oluwa;

13. On ni yio si kọ́ tempili Oluwa; on ni yio si rù ogo, yio si joko yio si jọba lori itẹ rẹ̀; on o si jẹ alufa lori itẹ̀ rẹ̀; ìmọ alafia yio si wà lãrin awọn mejeji.

14. Ade wọnni yio si wà fun Helemu, ati fun Tobijah, ati fun Jedaiah, ati fun Heni, ọmọ Sefaniah, fun iranti ni tempili Oluwa.

15. Awọn ti o jìna rére yio wá ikọle ni tempili Oluwa, ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rán mi si nyin. Yio si ri bẹ, bi ẹnyin o ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́ nitõtọ.

Ka pipe ipin Sek 6