Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 6:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, kẹkẹ́ mẹrin jade wá lati ãrin oke-nla meji; awọn oke-nla na si jẹ oke-nla idẹ.

2. Awọn ẹṣin pupa wà ni kẹkẹ́ ekini; ati awọn ẹṣin dudu ni kẹkẹ́ keji;

3. Ati awọn ẹṣin funfun ni kẹkẹ́ kẹta; ati awọn adikalà ati alagbara ẹṣin ni kẹkẹ́ kẹrin.

4. Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti mba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi, oluwa mi?

5. Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye.

6. Awọn ẹṣin dudu ti o wà ninu rẹ̀ jade lọ si ilẹ ariwa; awọn funfun si jade tẹ̀le wọn; awọn adíkalà si jade lọ si ihà ilẹ gusù.

7. Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye.

8. Nigbana ni on si kọ́ si mi, o si ba mi sọ̀rọ, wipe, Wò o, awọn wọnyi ti o lọ sihà ilẹ ariwa ti mu ẹmi mi parọrọ ni ilẹ ariwa.

9. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

Ka pipe ipin Sek 6