Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 5:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Angeli ti mba mi sọ̀rọ si jade lọ, o si wi fun mi pe, Gbe oju rẹ si oke nisisiyi, ki o si wò nkan yi ti o jade lọ.

6. Mo si wipe, Kini nì? O si wipe, Eyi ni òṣuwọn efà ti o jade lọ. O si wipe, Eyi ni àworan ni gbogbo ilẹ aiye.

7. Si kiyesi i, a gbe talenti ojé soke: obinrin kan si niyi ti o joko si ãrin òṣuwọn efa.

8. O si wipe, Eyi ni ìwa-buburu. O si jù u si ãrin òṣuwọn efa: o si jù òṣuwọn ojé si ẹnu rẹ̀.

9. Mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, obinrin meji jade wá, ẹfũfu si wà ninu iyẹ wọn; nitori nwọn ni iyẹ bi iyẹ àkọ: nwọn si gbe òṣuwọn efa na de agbedemeji aiye on ọrun.

10. Mo si sọ fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ pe, Nibo ni awọn wọnyi ngbe òṣuwọn efa na lọ?

11. O si wi fun mi pe, Lati kọ́ ọ ni ile ni ilẹ Ṣinari: a o si fi idi rẹ̀ mulẹ, a o si fi ka ori ipilẹ rẹ̀ nibẹ̀.

Ka pipe ipin Sek 5