Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 4:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Tani iwọ, Iwọ oke nla? iwọ o di pẹ̀tẹlẹ niwaju Serubbabeli: on o si fi ariwo mu okuta tenté ori rẹ̀ wá, yio ma kigbe wipe, Ore-ọfẹ, ore-ọfẹ si i.

8. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

9. Ọwọ Serubbabeli li o pilẹ ile yi; ọwọ rẹ̀ ni yio si pari rẹ̀; iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si nyin.

10. Ṣugbọn tani ha kẹgàn ọjọ ohun kekere? nitori nwọn o yọ̀, nwọn o si ri iwọ̀n lọwọ Serubbabeli pẹlu meje wọnni; awọn ni oju Oluwa, ti o nsare sihin sọhun ni gbogbo aiye.

11. Mo si dahun, mo si sọ fun u pe, Kini awọn igi olifi meji wọnyi jasi, ti o wà li apá ọtun fitilà ati li apá osì rẹ̀?

Ka pipe ipin Sek 4