Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 4:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ, pe, Kini wọnyi, Oluwa mi?

5. Angeli ti o mba mi sọ̀rọ dahùn o si wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, Nkò mọ̀, oluwa mi.

6. O si dahùn o si wi fun mi pe, Eyi ni ọ̀rọ Oluwa si Serubbabeli wipe, Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

7. Tani iwọ, Iwọ oke nla? iwọ o di pẹ̀tẹlẹ niwaju Serubbabeli: on o si fi ariwo mu okuta tenté ori rẹ̀ wá, yio ma kigbe wipe, Ore-ọfẹ, ore-ọfẹ si i.

8. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

9. Ọwọ Serubbabeli li o pilẹ ile yi; ọwọ rẹ̀ ni yio si pari rẹ̀; iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si nyin.

10. Ṣugbọn tani ha kẹgàn ọjọ ohun kekere? nitori nwọn o yọ̀, nwọn o si ri iwọ̀n lọwọ Serubbabeli pẹlu meje wọnni; awọn ni oju Oluwa, ti o nsare sihin sọhun ni gbogbo aiye.

Ka pipe ipin Sek 4